56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì.
57 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì (ìlú ti ààbò), àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà,
58 Hílénì Débírì,
59 Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.
60 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀.
61 Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.
62 Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.