67 Ní òkè orílẹ̀ èdè Éfíráímù, a fún wọn ní Ṣékémù (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Géṣérì
68 Jókíméámù, Bétì-Hórónì.
69 Áíjálónì àti Gátì Rímónì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
70 Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ádérì àti Bíléámù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kóhátítè.
71 Àwọn ará Géríṣónítè gbà nǹkan wọ̀nyí:Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè wọ́n gba Gólánì ní Básánì àti pẹ̀lú Áṣítarótì, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;
72 Láti ẹ̀yà Ísákárìwọ́n gba Kádéṣì, Dábérátì
73 Rámótì àti Ánénù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;