13 Àwọn ọmọ Náfítalì:Jáhíṣíẹ́lì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílémù—ọmọ Rẹ̀ nípa Bílíhà.
14 Àwọn ìran ọmọ Mánásè:Ásíríélì jẹ́ ìran ọmọ Rẹ̀ nípa sẹ̀ àlè Rẹ̀ ará Árámù ó bí Mákírì baba Gílíádì.
15 Mákírì sì mú ìyàwó láti àárin àwọn ará Hípímù àti Ṣúpímù. Orúkọ arábìnrin Rẹ̀ a má a jẹ́ Máákà.Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a má a jẹ́ Ṣélóféhádì, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.
16 Máákà, ìyàwó Mákírì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ Rẹ̀ ní Pérésì. Ó sì pe arákùnrin Rẹ̀ ní Ṣéréṣì, àwọn ọmọ Rẹ̀ sì ní Úlámù àti Rákémù.
17 Ọmọ Úlámù:Bédánì.Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè.
18 Arábìnrin Rẹ̀. Hámólékétì bí Ṣíhódì, Ábíésérì àti Máhíláhì.
19 Àwọn ọmọ Ṣémídà sì jẹ́:Áhíánì, Ṣékémù, Líkì àti Áníámù.