17 Ọmọ Úlámù:Bédánì.Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè.
18 Arábìnrin Rẹ̀. Hámólékétì bí Ṣíhódì, Ábíésérì àti Máhíláhì.
19 Àwọn ọmọ Ṣémídà sì jẹ́:Áhíánì, Ṣékémù, Líkì àti Áníámù.
20 Àwọn ìran ọmọ Éfíráímù:Ṣútéláhì, Bérédì ọmọkùnrin Rẹ̀,Táhátì ọmọ Rẹ̀, Éléádáhì ọmọ Rẹ̀.
21 Táhátì ọmọ Rẹ̀ Ṣábádì ọmọ, Rẹ̀,àti Ṣútéláhì ọmọ Rẹ̀.Éṣérì àti Éléádì ni a pá nípaṣẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gátì Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn
22 Éfíráímù baba wọn sọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan Rẹ̀ wá láti tù ú nínú.
23 Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó Rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Béríà nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.