2 Àwọn ọmọ Tólà:Húsì, Réfáíáhì, Jéríélì, Jámáì, Jíbísámù àti Ṣámúẹ́lì Olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dáfídì, àwọn ìran ọmọ Tólà tò lẹ́sẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ẹgbẹ̀ta (22,600).
3 Àwọn ọmọ, Húṣì:Ísíráhíà.Àwọn ọmọ Ísíráhíà:Míkáélì Ọbádáyà, Jóẹ́lì àti Ísíhíáhì. Gbogbo àwọn máràrùn sì jẹ́ olóyè.
4 Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mérìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó
5 Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Ísákárì, bí a ti tò ó lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlàádórin ni gbogbo Rẹ̀.
6 Àwọn ọmọ mẹ́ta Bẹ́ńjámínì:Bélà, Békérì àti Jédíáélì.
7 Àwọn ọmọ Bélà:Éṣíbónì, Húṣì, Ísíélì, Jérómótì àti Írì, àwọn máràrùnún. Awọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbàámọ́kànlá-ó-lé-mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn (22,034)
8 Àwọn ọmọ Békérì:Ṣémíráhì, Jóáṣì, Élíásérì, Élíóénáì, omírì, Jeremótù Ábíjà, Ánátótì àti Álémétì Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Békérì