12 Àwọn ọmọ Élípálì:Ébérì, Míṣámì, Ṣémédù (ẹni tí ó kọ́ Ónò àti Lódì pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká Rẹ̀.)
13 Pẹ̀lú Béríà àti Ṣémà, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Áíjálónì àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gátì kúrò.
14 Áhíò, Ṣásákì Jérémílò,
15 Ṣébádíà, Árádì, Édérì
16 Míkáélì Íṣífà àti Jóhà jẹ́ àwọn ọmọ Béríà.
17 Ṣébàdíáhì, Mésúlámù Hésékì, Hébérì
18 Íṣíméráì, Íṣílíáhì àti Jóbábì jẹ́ àwọn ọmọ Élípálì.