8 A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣáháráímù ní Móábù lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó Rẹ̀ sílẹ̀, Húṣímù àti Báárà.
9 Nípaṣẹ̀ ìyàwó Rẹ̀ Hódéṣì ó ní Jóbábù ṣíbíà, Méṣà, Málíkámà,
10 Jéúṣì Ṣákíà àti Mírímà. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
11 Nípaṣẹ̀ Húṣímù ó ní Ábítúbù àti Élípálì.
12 Àwọn ọmọ Élípálì:Ébérì, Míṣámì, Ṣémédù (ẹni tí ó kọ́ Ónò àti Lódì pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká Rẹ̀.)
13 Pẹ̀lú Béríà àti Ṣémà, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Áíjálónì àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gátì kúrò.
14 Áhíò, Ṣásákì Jérémílò,