21 Ṣékáríà, ọmọ Méṣélémíà jẹ́ Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní à bá wọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.
22 Gbogbo Rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní àwọn ìlóró ẹnu ọ̀nà jẹ́ ìgba o lé méjìlá (212). A kòmọ̀-ọ́n fún ìràntí nípa ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní àwọn ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò ìgbàgbọ́ wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Ṣámúẹ́lì aríran.
23 Àwọn àti àtẹ̀lé wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́.
24 Àwọn olùtọ́ju ẹnu ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn àríwá àti gúsù.
25 Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín isẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.
26 Ṣùgbọ́n àwọn olórí olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Léfì ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìsúra ní ilé Olúwa.
27 Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Olúwa ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.