9 Àwọn ènìyàn láti Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rùn ún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.
10 Ní ti àwọn àlùfáà:Jédáíà; Jéhóíáríbì; Jákínì;
11 Áṣáríyà ọmọ Hílíkíyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Méráíótù, ọmọ Áhítúbì, onísẹ́ tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;
12 Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Páṣúrì, ọmọ Málíkíjà; àti Másáì ọmọ Ádíélì, ọmọ Jáhíṣérà, ọmọ Mésúlámù ọmọ Méṣílémítì, ọmọ Ímérì
13 Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.
14 Níti àwọn ará Léfì:Ṣémáíà ọmọ Hásíhúbì, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíà ará Mérárì:
15 Bákíbákárì, Héréṣì, Gálálì àti Mátaníyà, ọmọ Míkà, ọmọ Ṣíkírì, ọmọ Ásáfù;