2 Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ẹ jẹ́ kí a wá ọ̀dọ́mọbìnrin wúndíá kan kí ó dúró ti ọba, kì ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Kí ó dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀ kí ara ọba Olúwa wa lè móoru.”
3 Nígbà náà ni wọ́n lọ jákèjádo ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti wá ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà, wọ́n sì rí Ábíságì, ará Ṣúnémù, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọba.
4 Ọmọbìnrin náà rẹwà gidigidi; ó sì ń ṣe ìtọ́jú ọba, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n ọba kò sì bá a lò pọ̀.
5 Àdóníjà ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Hágátì sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì sètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀.
6 (Baba rẹ̀ kò bà á nínú jẹ́ rí nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi hùwà báyìí?” Ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin, òun ni a bí lé Ábúsálómù.)
7 Àdóníjà sì gbérò pẹ̀lú Jóábù, ọmọ Ṣérúyà àti Ábíátarì àlùfáà, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un.
8 Ṣùgbọ́n Ṣádókù àlùfáà, Bẹ́náyà ọmọ Jóhóíádà, Nátanì wòlíì, Ṣímè àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rélì àti olórí ogun Dáfídì ni kò darapọ̀ mọ́ Àdóníjà