1 Ọba 8 BMY

A Gbé Àpótí-Ẹ̀rí Wá Sí Ilé Náà.

1 Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbà Ísírẹ́lì àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ papọ̀ níwájú rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù, láti gbé àpótí-ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá láti ìlú Dáfídì, tí ń ṣe Ṣíónì.

2 Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì pe ara wọn jọ sọ́dọ̀ Sólómónì ọba ní àkókò àjọ ọdún ní oṣù Étanímù tí íṣe osù kéje.

3 Nígbà tí gbogbo àwọn àgbà Ísírẹ́lì dé, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí-ẹ̀rí,

4 wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa àti àgọ́ àjọ ènìyàn àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sì gbé wọn gòkè wá,

5 Àti Sólómónì ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí-ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rúbọ.

6 Àwọn àlùfáà sì gbé àpótí-ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀ sínú ibi tí a yà sí mímọ́, ibi mímọ́ ilé náà, jùlọ lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.

7 Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí-ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí-ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e.

8 Àwọn ọ̀pá yìí ga tó bẹ́ẹ̀ tí a fi le rí orí wọn láti ibi mímọ́ níwájú ibi tí a yà sí mímọ́, ṣùgbọ́n a kò sì rí wọn lóde ibi mímọ́, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.

9 Kò sí ohun kankan nínú àpótí-ẹ̀rí bí kò ṣe tábìlì òkúta méjì tí Mósè ti fi sí ibẹ̀ ní Hórébù, níbi tí Olúwa ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

10 Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́, àwọ̀sánmà sì kún ilé Olúwa.

11 Àwọn àlùfáà kò sì le ṣiṣẹ́ wọn nítorí àwọ̀sánmà náà, nítorí ògo Olúwa kún ilé náà.

12 Nígbà náà ni Sólómónì sì wí pé, “Olúwa ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri;

13 Nítòótọ́ èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé.”

14 Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn.

15 Nígbà náà ni ó wí pé:“Ìbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé,

16 ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dáfídì láti ṣàkóso àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’

17 “Dáfídì baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

18 Ṣùgbọ́n Olúwa sì wí fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ.

19 Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde; òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’

20 “Olúwa sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́: Èmi sì ti rọ́pò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì báyìí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

21 Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí-ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú Olúwa tí ó ti bá àwọn baba wa dá nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.”

Àdúrà Sólómónì Fún Ìyàsímímọ́

22 Sólómónì sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run.

23 Ó sì wí pé:“Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.

24 O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí.

25 “Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì bàbá mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, Iwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsí ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn.

26 Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì baba mi wá sí ìmúṣẹ.

27 “Ṣùgbọ́n nítòótọ́ Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ!

28 Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí.

29 Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí ṣí ilé yìí ní òru àti ní ọ̀sán, ibí yìí tí ìwọ ti wí pé, óorúkọ mi yóò wà níbẹ̀, nítorí ìwọ yóò gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ gbà sí ibí yìí.

30 Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjìn.

31 “Nígbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì fi wá lée láti mú-un búra, bí ìbúra náà bá sì dé iwájú pẹpẹ rẹ ní ilé yìí,

32 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtọ́ láre, kí a sì fi ẹṣẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀.

33 “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí

34 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ jìn-ní, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn.

35 “Nígbà tí ọ̀run bá ṣé mọ́, tí kò sí òjò nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,

36 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jìn wọ́n, à ní Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní.

37 “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdú, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí àrùnkárùn tó lè wá,

38 nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí,

39 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjìn, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn,

40 Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa.

41 “Níti àwọn àlejò tí kì í ṣe Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ,

42 nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí,

43 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.

44 “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀ta wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ,

45 nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.

46 “Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jínjìnnà tàbí nítòòsí;

47 bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ, wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú’;

48 bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ;

49 Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró.

50 Kí o sì dáríjìn àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn;

51 nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Éjíbítì jáde wá, láti inú irin ìléru.

52 “Jẹ́ kí ojú rẹ sí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ.

53 Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ lati ọwọ́ Móṣè ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ Olúwa Ọlọ́run mú àwọn baba wa ti Éjíbítì jáde wá.”

54 Nígbà tí Sólómónì ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run

55 Ó sì dìde dúró ó sì fi ohùn rara súre fún gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì wí pé:

56 “Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ wá.

57 Kí Olúwa Ọlọ́run wa kí ó wà pẹ̀lú wa bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn baba wa; kí ó má sì ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kọ̀ wá sílẹ̀.

58 Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn bàbá wa.

59 Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa, kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́,

60 kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn.

61 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí.”

Ìyàsí mímọ́ ilé náà.

62 Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Ísírẹ́lì rú ẹbọ níwájú Olúwa.

63 Sólómónì rú ẹbọ ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbàá mọ́kànlá (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn omọ Ísírẹ́lì ya ilé Olúwa sí mímọ́.

64 Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárin tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ọrẹ ṣíṣun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.

65 Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe àpèjọ nígbà náà, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hámátì títí dé odò Éjíbítì. Wọ́n sì sàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ijọ́ méje àti ijọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.

66 Ní ọjọ́ kẹjọ ó rán àwọn ènìyàn lọ. Wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn fún gbogbo ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, àti fún Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22