1 Ọba 15 BMY

Ábíjà Ọba Júdà

1 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù ọmọ Nébátì, Ábíjà jọba lórí Júdà,

2 ó sì jọba ní ọdún mẹ́ta ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù.

3 Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀; ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbáńlá rẹ̀ ti ṣe.

4 Ṣùgbọ́n, nítorí i Dáfídì Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jérúsálẹ́mù nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀.

5 Nítorí tí Dáfídì ṣe èyí tí ó dára ní ojú Olúwa, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí Olúwa pa láṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Ùráyà ará Hítì.

6 Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní gbogbo ọjọ́ ayé Ábíjà.

7 Níti ìyókù ìṣe Ábíjà, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò há kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ogun sì wà láàrin Ábíjà àti Jéróbóámù.

8 Ábíjà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì. Áṣà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Áṣà Ọba Júdà

9 Ní ogún ọdún Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Áṣà jọba lórí Júdà,

10 Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù.

11 Áṣà sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dáfídì baba rẹ̀ ti ṣe.

12 Ó sì mú àwọn tí ń ṣe panṣágà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò.

13 Ó sì mú Máákà ìyá ìyá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún òrìṣà rẹ̀. Áṣà sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún níbi odò Kídírónì.

14 Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Áṣà pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.

15 Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa

16 Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn.

17 Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì sì gòkè lọ sí Júdà, ó sì kọ́ Rámà láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Áṣà ọba lọ.

18 Nígbà náà ni Áṣà mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Bẹni-Hádádì ọmọ Tábírímónì, ọmọ Hésíónì ọba Síríà tí ó ń gbé ní Dámásíkù.

19 Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrin èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrin bàbá mi àti bàbá rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”

20 Bẹni-Hádádì gba ti Áṣà ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì. Ó sì ṣẹ́gun Íjónì, Dánì àti Abeli-Bẹti-Máákà, àti gbogbo Kénérótì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náfútalì.

21 Nígbà tí Bááṣà sì gbọ́ èyí, ó sì síwọ́ kíkọ́ Rámà, ó sì lọ kúrò sí Tírísà.

22 Nígbà náà ni Áṣà ọba kéde ká gbogbo Júdà, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta àti igi tí Bááṣà ń lò kúrò ní Rámà. Áṣà ọba sì fi wọ́n kọ́ Gébà ti Bẹ́ńjámínì àti Mísípà.

23 Níti ìyókù gbogbo ìṣe Áṣà, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, àrùn ṣe é ní ẹṣẹ̀ rẹ̀.

24 Áṣà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀ ní ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀. Jèhóṣáfátì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Nádábù Ọba Ísírẹ́lì

25 Nádábù ọmọ Jéróbóámù sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Áṣà ọba Júdà, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjì.

26 Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó mú Ísírẹ́lì dá.

27 Bááṣà ọmọ Áhíjà ti ilé Ísákárì sì dìtẹ̀ sí i, Bááṣà sì kọlù ú ní Gíbétónì, ìlú àwọn ará Fílístínì, nígbà tí Nádábù àti gbogbo Ísírẹ́lì dó ti Gíbétónì.

28 Bááṣà sì pa Nádábù ní ọdún kẹta Áṣà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀.

29 Ó sì ṣe, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba ó pa gbogbo ilé Jéróbóámù, kò sì ku ẹnìkan tí ń mí fún Jéróbóámù, ṣùgbọ́n ó run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ó sọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Áhíjà ará Ṣílò:

30 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jéróbóámù ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, àti nítorí tí ó ti mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.

31 Níti ìyókù ìṣe Nádábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?

32 Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ wọn.

Bááṣà Ọba Ísírẹ́lì

33 Ní ọdún kẹta Áṣà ọba Júdà, Bááṣà ọmọ Áhíjà sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Tírísà, ó sì jọba ní ọdún mẹ́rìnlélógún.

34 Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Jéróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22