1 Nígbà tí Solómónì sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe,
2 Olúwa sì farahàn án ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gíbíónì.
3 Olúwa sì wí fún un pé:“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.
4 “Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dáfídì baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́,
5 Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dáfídì baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’
6 “Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin Ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,
7 nígbà náà ni èmi yóò ké Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè.
8 Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’
9 Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn bàbá wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n sì ti gbá Ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ”
10 Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Sólómónì kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba.
11 Sólómónì ọba sì fi ogún ìlú ní Gálílì fún Hírámù ọba Tírè, nítorí tí Hírámù ti bá a wá igi kédárì àti igi fírì àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀.
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Hírámù sì jáde láti Tírè lọ wo ìlú tí Sólómónì fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn.
13 Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nì wọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ kábúlù títí fi di òní yìí.
14 Hírámù sì ti fi ọgọ́fà (120) talẹ́ntì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.
15 Ìdí àwọn asìnrú ti Sólómónì ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkárarẹ̀; Mílò, odi Jérúsálẹ́mù, Hásórì, Mégídò àti Gésérì.
16 Fáráò ọba Éjíbítì sì ti kọlu Gésérì, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kénánì tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Sólómónì lọ́rẹ.
17 Sólómónì sì tún Gésérì kọ́, àti Bẹti Hórónì ìṣàlẹ̀,
18 Àti Bálátì àti Támárì ní ihà, láàrin rẹ̀,
19 Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Sólómónì ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ní Lébánónì àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.
20 Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Ámórì ará Hítì, Pérísì, Hífì àti Jébúsì, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Ísírẹ́lì,
21 ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò le parun pátapáta, àwọn ni Sólómónì bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.
22 Ṣùgbọ́n, Sólómónì kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀.
23 Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Sólómónì, àádọ́tàdínlẹ́gbẹ̀ta (550), ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà.
24 Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Fáráò ti gòkè láti ìlú Dáfídì wá sí ààfin tí Sólómónì kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Mílò.
25 Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Sólómónì ń rú ẹbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún Olúwa, ó sì sun tùràrí níwájú Olúwa pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà.
26 Sólómónì ọba sì tún ṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Gébérì, tí ó wà ní ẹ̀bá Élátì ní Édómù, létí òkun pupa.
27 Hírámù sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì.
28 Wọ́n sì dé ófírì, wọ́n sì mú irínwó ó lé ogún (420) talẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Sólómónì ọba.