1 Ọba 7 BMY

Sólómónì Kọ́ Ààfin Rẹ̀

1 Sólómónì sì lo ọdún mẹ́talá láti fi kọ́ ààfin rẹ̀, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ ààfin rẹ̀.

2 Ó kọ́ ilé igbó Lébánónì pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kédárì, àti ìdábú igi kédárì lórí òpó náà.

3 A sì fi igi kédárì tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ̀n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀dógún ní ọ̀wọ́.

4 Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn.

5 Gbogbo ilẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn.

6 Ó sì fi ọ̀wọ̀n ṣe gbàngàn ìdájọ́: àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn.

7 Ó sì ṣe gbàngàn ìtẹ́, gbàngàn ìdájọ́, níbi tí yóò ti ṣe ìdájọ́, ó sì fi igi kédárì bò ó láti ilẹ̀ dé àjà ilé.

8 Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n. Sólómónì sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Fáráò tí ó ní ní aya.

9 Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde.

10 Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńlá ńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ̀wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ.

11 Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbé àti igi kédárì.

12 Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kédárì, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé Olúwa pẹ̀lú ìloro rẹ̀.

Ọ̀ṣọ́ Tẹ́ḿpìlì

13 Sólómónì ọba ránṣẹ́ sí Tírè, ó sì mú Hírámù wá,

14 ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Náfítalì àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tírè, alágbẹ̀dẹ idẹ. Hírámù sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ idẹ. Ó wá sọ́dọ̀ Sólómónì ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un.

15 Ó sì dá ọ̀wọ̀n idẹ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún ní gíga okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ni ó sì yí wọn ká.

16 Ó sì tún ṣe ìparí méjì ti idẹ dídá láti fi sókè àwọn ọ̀wọ̀n náà, ìparí kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga.

17 Onírúurú iṣẹ́, àti ohun híhun ẹ̀wọ̀n fún àwọn ìparí tí ń bẹ lórí àwọn ọ̀wọ̀n náà, méje fún ìparí kọ̀ọ̀kan.

18 Ó sì ṣe àwọn Pómégíránátè ní ọ̀wọ́ méjì yíkákiri lára iṣẹ́ ọ̀wọ̀n náà, láti fi bo àwọn ìparí ti ń bẹ lókè, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìparí kejì.

19 Àwọn ìparí tí ń bẹ ní òkè àwọn ọ̀wọ̀n náà tí ń bẹ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ náà dàbí àwòrán lílì, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga.

20 Lórí àwọ̀n ìparí ọ̀wọ́n méjì náà lókè, wọ́n sì súnmọ́ ibi tí ó yẹ lára ọ̀wọ̀n tí ó wà níbi iṣẹ́ àwọ̀n, wọ́n sì jẹ́ igba (200) pómégíránátè ní ọ̀wọ́ yíkákiri.

21 Ó sì gbé àwọn ọ̀wọn náà ró ní ìloro tẹ́ḿpìlì, ó sì pe orúkọ ọ̀wọ̀n tí ó wà ní gúṣù ní Járánì àti èyí tí ó wà ní àríwá ní Bóásì.

22 Àwọn ìparí lókè sì jẹ́ àwòrán lílì. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ti àwọn ọ̀wọ̀n sì parí.

23 Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ̀n yíí ká.

24 Ní ìṣàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wà yíi ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a.

25 Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúṣù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà oòrùn. Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú.

26 Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì. Ó sì gba ẹgbàá (2,000) ìwọ̀n Bátì.

27 Ó sì tún ṣe ẹṣẹ̀ idẹ tí a lè gbé mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga.

28 Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà: Wọ́n ní àlàfo ọnà àárin tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí.

29 Lórí àlàfo ọnà àárin tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà.

30 Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀.

31 Nínú ẹsẹ̀ náà ẹnu kan wà tí ó kọ bíríkítí tí ó jìn ní ìgbọ̀nwọ́ kan. Ẹnu yìí ṣe róbótó àti pẹ̀lú iṣẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. Ní àyíká ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbígbẹ́ wà. Àlàfo ọ̀nà àárin ẹsẹ̀ náà sì ní igun mẹ́rin, wọn kò yíká.

32 Kẹ̀kẹ́ mẹ́rin sì wà nísàlẹ̀ àlàfo ọ̀nà àárin a sì so ọ̀pá àyíká kẹ̀kẹ́ náà mọ́ ẹsẹ̀ náà. Gíga àyíká kẹ̀kẹ́ kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.

33 A sì ṣe àyíká kẹ̀kẹ́ náà bí i iṣẹ́ kẹ̀kẹ́; igi ìdalu, ibi ihò, ibi ìpàdé, àti ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, gbogbo wọn sì jẹ́ irin dídà.

34 Ẹṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ mẹ́rin, ọ̀kan ní igun kọ̀ọ̀kan, tí ó yọrí jáde láti ẹṣẹ̀.

35 Lókè ẹṣẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn. Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárin rẹ̀ ni a ṣo mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà.

36 Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ sára ìhà orí rẹ̀ àti sára àlàfo ọ̀nà àárin, ní gbogbo ibi tí àyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri.

37 Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wàá. Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà.

38 Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n Bátì, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà.

39 Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn ún sí apá ọ̀tún ìhà gúṣù ilé náà àti márùn ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà oòrùn sí ìdojúkọ gúṣù ilé náà.

40 Ó sì tún ṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwo kòtò.Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Sólómónì ọba:

41 Àwọn ọ̀wọ̀n méjì;Ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ̀n iṣẹ́;àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ̀n;

42 Irínwó (400) pómégíránátè fún iṣẹ́ àwọn méjì, ọ̀wọ́ méjì pómégíránátè fún iṣẹ́ àwọn kan láti bo àwọn ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ̀n;

43 Ẹṣẹ̀ mẹ́wàá pẹ̀lú agbádá mẹ́wàá wọn;

44 Agbada ńlá náà, àti màlúù méjìlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀;

45 Ìkòkò, ọkọ́ àti àwo kòtò.Gbogbo ohun èlò wọ̀nyí tí Hírámù ṣe fún Sólómónì ọba nítorí iṣẹ́ Olúwa sì jẹ́ idẹ dídán.

46 Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì lágbedeméjì Ṣúkótì àti Ṣárítanì.

47 Sólómónì sì jọ̀wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí láìwọ̀n, nítorí tí wọ́n pọ̀ jù; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ìwọ̀n idẹ.

48 Sólómónì sì tún ṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú:pẹpẹ wúrà;tabílì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà;

49 Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko;fìtílà àti ẹ̀mú wúrà;

50 Ọpọ́n kìkì wúrà, àlùmágàjí fìtílà, àti àwo kòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára;àti àgbékọ́ wúrà fún ilẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ilẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹ́ḿpìlì.

51 Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dáfídì baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22