1 Sólómónì ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò, àwọn ọmọbìnrin Móábù, àti ti Ámónì, ti Édómù, ti Sídónì àti ti àwọn ọmọ Hítì.
2 Wọ́n wá láti orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀ síbẹ̀ Sólómónì fà mọ́ wọn ní ìfẹ́.
3 Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrun (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà.
4 Bí Sólómónì sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.
5 Ó tọ Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì lẹ́yìn, àti Mílíkómì òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì.
6 Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe búburú níwájú Olúwa; kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.
7 Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jérúsálẹ́mù, Sólómónì kọ́ ibi gíga kan fún Kémósì, òrìṣà ìríra Móábù, àti fún Mólékì, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì.
8 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rúbọ fún òrìṣà wọn.
9 Olúwa bínú sí Sólómónì nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì.
10 Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Sólómónì kí ó má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Sólómónì kò pa àṣẹ Olúwa mọ́.
11 Nítorí náà Olúwa wí fún Sólómónì pé, “Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmìíràn.
12 Ṣùgbọ́n, nítorí Dáfídì baba rẹ, Èmi kì yóò ṣe é ní ọjọ́ rẹ. Èmi yóò fà á ya kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ.
13 Síbẹ̀ èmi kì yóò fa gbogbo ìjọba náà ya, ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, àti nítorí Jérúsálẹ́mù tí èmi ti yàn.”
14 Nígbà náà ni Olúwa gbé ọ̀ta kan dìde sí Sólómónì, Hádádì ará Édómù ìdílé ọba ni ó ti wá ní Édómù.
15 Ó sì ṣe, nígbà tí Dáfídì wà ní Édómù, Jóábù olórí ogun sì gòkè lọ láti sìn àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Édómù.
16 Nítorí Jóábù àti gbogbo Ísírẹ́lì sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, títí wọ́n fi pa gbogbo ọkùnrin Édómù run.
17 Ṣùgbọ́n Hádádì sá lọ sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn ará Édómù tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ bàbá rẹ̀. Hádádì sì wà ní ọmọdé nígbà náà.
18 Wọ́n sì dìde kúrò ní Mídíánì, wọ́n sì lọ sí Páránì. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Páránì wá, wọ́n sì lọ sí Éjíbítì, sọ́dọ̀ Fáráò ọba Éjíbítì ẹni tí ó fún Hádádì ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ.
19 Inú Fáráò sì dùn sí Hádádì púpọ̀ tí ó fi fún un ní arábìnrin aya rẹ̀ ní aya, arábìnrin Tápénésì, ayaba.
20 Arábìnrin Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Génúbátì, ẹni tí Tápénésì tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Génúbátì ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Fáráò fún ra rẹ̀.
21 Nígbà tí ó sì wà ní Éjíbítì, Hádádì sì gbọ́ pé Dáfídì ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Jóábù olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú. Nígbà náà ni Hádádì wí fún Fáráò pé, “Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi.”
22 Fáráò sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?”Hádádì sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!”
23 Ọlọ́run sì gbé ọ̀ta mìíràn dìde sí Sólómónì, Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hádádésérì olúwa rẹ̀, ọba Sóbà.
24 Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dáfídì fi pa ogun Sóbà run; wọ́n sì lọ sí Dámásíkù, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jọba ní Dámásíkù.
25 Résónì sì jẹ́ ọ̀ta Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì, ó ń pa kún ibi ti Hádádì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Résónì jọba ní Síríà, ó sì sòdì sí Ísírẹ́lì.
26 Bákan náà Jéróbóámù ọmọ Nébátì sì sọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì, ará Éfúrátì ti Sérédà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Sérúà.
27 Èyí sì ni ìdí tí ó fi sọ̀tẹ̀ sí ọba: Sólómónì kọ́ Mílò, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dáfídì baba rẹ̀.
28 Jéróbóámù jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Sólómónì sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Jóṣẹ́fù.
29 Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jéróbóámù ń jáde kúrò ní Jérúsálẹ́mù. Wòlíì Áhíjà ti Ṣílò sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá túntún. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko,
30 Áhíjà sì gbá agbádá túntún tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá
31 Nígbà náà ni ó sọ fún Jéróbóámù pé, “Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómónì, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.
32 Ṣùgbọ́n nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, òun yóò ní ẹ̀yà kan.
33 Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì, Kémósì òrìṣà àwọn ará Móábù, àti Mííkámù òrìṣà àwọn ọmọ Ámónì, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómónì ti ṣe.
34 “ ‘Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Sólómónì; èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́.
35 Èmi yóò gba ìjọba náà ní ọwọ́ ọmọ rẹ̀, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ̀wàá fún ọ.
36 Èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa ní ìmọ́lẹ̀ níwájú mi nígbà gbogbo ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn láti fi orúkọ mi síbẹ̀.
37 Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, Èmi yóò mú ọ, ìwọ yóò sì jọba lórí ohun gbogbo tí ọkàn rẹ ń fẹ́; ìwọ yóò jọba lórí Ísírẹ́lì.
38 Bí ìwọ bá ṣe gbogbo èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú mi nípa pípa òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí i Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò kọ́ ilé òtítọ́ fún ọ bí èyí tí mo kọ́ fún Dáfídì, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì fún ọ.
39 Èmi yóò sì rẹ irú ọmọ Dáfídì sílẹ̀ nítorí èyí, ṣùgbọ́n kì í ṣe títí láé.’ ”
40 Sólómónì wá ọ̀nà láti pa Jéróbóámù, ṣùgbọ́n Jéróbóámù sá lọ sí Éjíbítì, sọ́dọ̀ Ṣísákì ọba Éjíbítì, ó sì wà níbẹ̀ títí Sólómónì fi kú.
41 Ìyòókù iṣẹ́ Sólómónì àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìṣe Sólómónì bí?
42 Sólómónì sì jọba ní Jérúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní ogójì ọdún.
43 Nígbà náà ni ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì baba rẹ̀. Réhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.