1 Ọba 18 BMY

Èlíjà àti Ọbadíà

1 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà wá pé: “Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Áhábù, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.”

2 Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ fi ara rẹ̀ han Áhábù.Ìyàn ńlá sì mú ní Samáríà,

3 Áhábù sì ti pe Ọbadíàh, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀. Ọbadíà sì bẹ̀rù Olúwa gidigidi.

4 Nígbà tí Jésébélì sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Ọbadíà sì mú ọgọ́rùn ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.

5 Áhábù sì ti wí fún Ọbadíà pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹsin àti àwọn ìbááka là, kí a má báà ṣòfò àwọn ẹranko pátapáta.”

6 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrin ara wọn, Áhábù gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadíà sì gba ọ̀nà mìíràn lọ.

7 Bí Ọbadíà sì ti ń rìn lọ, Èlíjà sì pàdé rẹ̀. Ọbadíà sì mọ̀ ọ́, ó dojú bolẹ̀, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ní tòótọ́, Èlíjà, Olúwa mi?”

8 Èlíjà sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, lọ kí o sọ fún olúwa rẹ pé, ‘Èlíjà ń bẹ níhìn ín.’ ”

9 Ọbadíà sì béèrè pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ kí ni mo ha dá tí ìwọ fi ń fi ìránṣẹ́ rẹ lé Áhábù lọ́wọ́ láti pa?

10 Mo mọ̀ dájú pé bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ.

11 Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, ìwọ wí fún mi pé kí n lọ sọ́dọ̀ olúwa mi, kí n sì wí pé, ‘Èlíjà ń bẹ níhìn ín.’

12 Èmi kò sì mọ ibi tí ẹ̀mí Olúwa yóò gbé ọ lọ nígbà tí mo bá fi ọ́ sílẹ̀. Bí mo bá lọ, tí mo sì sọ fún Áhábù, tí kò sì rí ọ, òun a sì pa mí. Ṣíbẹ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ bẹ̀rù Olúwa láti ìgbà èwe mi wá.

13 Ṣé Olúwa mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jésébélì ń pa àwọn wòlíì Olúwa? Mo fi ọgọ́rùn ún wòlíì Olúwa pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn.

14 Ìwọ sì sọ fún mi nísinsìn yìí pé, kí n tọ olúwa mi lọ pé, ‘Èlíjà ń bẹ níhìn ín.’ Òun a sì pa mí!”

15 Èlíjà sì wí pé, “Bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, ní tòótọ́ èmi yóò fi ara mi hàn fún Áhábù lónìí.”

Èlíjà Lórí Òkè Kámẹ́lì.

16 Bẹ́ẹ̀ ni Ọbadíà sì lọ láti pàdé Áhábù, ó sì sọ fún un, Áhábù sì lọ láti pàdé Èlíjà.

17 Nígbà tí ó sì rí Èlíjà, ó sì wí fún un pé, “Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu?”

18 Èlíjà sì dá a lóhùn pé, “Èmi kò yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé bàbá rẹ. Ẹ ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Báálímù lẹ́yìn.

19 Nísinsìn yìí kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti pàdé mi lórí òkè Kámẹ́lì. Àti kí o sì mú àádọ́tàlénírinwó (450) àwọn wòlíì Báálì àti irinwó (400) àwọn wòlíì ère òrìṣà tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jésébélì.”

20 Bẹ́ẹ̀ ni Áhábù ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì kó àwọn wòlíì jọ sí orí òkè Kámẹ́lì.

21 Èlíjà sì lọ ṣíwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì? Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan.

22 Nígbà náà ni Èlíjà wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa, ṣùgbọ́n, àádọ́tàlénírinwó (450) ni wòlíì Báálì.

23 Ẹ fún wa ní ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì ké e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i.

24 Nígbà náà ẹ ó sì képe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì képe orúkọ Olúwa. Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run.”Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára.”

25 Èlíjà sì wí fún àwọn wòlíì Báálì wí pé, “Ẹ yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀. Ẹ ké pe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i.”

26 Nígbà náà ni wọ́n sì mú ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù náà, tí a ti fi fún wọn, wọ́n sì ṣe é.Nígbà náà ni wọ́n sì képe orúkọ Báálì láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan wí pé, “Báálì! Dáwa lóhùn!” Wọ́n sì ń kégbe. Ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn; kò sí ẹnìkan tí ó sì dáhùn. Wọ́n sì jó yí pẹpẹ náà ká, èyí tí wọ́n tẹ́.

27 Ní ọ̀sán gangan, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, “Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run ṣá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò. Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i.”

28 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn.

29 Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì sí ìdáhùn, kò sì sí ẹni tí ó kà á sí.

30 Nígbà náà ni Èlíjà wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi.” Wọ́n sì sún mọ́ ọn, ó sì tún pẹpẹ Olúwa tí ó ti wó lulẹ̀ ṣe.

31 Èlíjà sì mú òkúta méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà ọmọ Jákọ́bù kan, ẹni tí ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wá wí pé, “Ísírẹ́lì ni orúkọ rẹ̀ yóò máa jẹ́.”

32 Ó sì tẹ́ pẹpẹ pẹ̀lú àwọn òkúta wọ̀nyí ní orúkọ Olúwa, ó sì wa yàrá yí pẹpẹ náà ká, tí ó lè gba ìwọ̀n òṣùwọ̀n irúgbìn méjì.

33 Ó sì to igi náà dáradára, ó sì ké ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù náà wẹ́wẹ́, ó sì tò ó sórí igi. Nígbà náà ni ó sì wí fún wọn wí pé, “Ẹ fi omi kún ìkòkò mẹ́rin, kí ẹ sì tun sórí ẹbọ sísun àti sórí igi náà.”

34 Ó sì wí pe, “Ẹ ṣe é ní ìgbà kejì” Wọ́n sì ṣe é ní ìgbà kejì.Ó sì tún wí pé, “Ṣe é ní ìgbà kẹta.”

35 Omi náà sì ṣàn yí pẹpẹ náà ká, ó sì fi omi kún yàrà náà pẹ̀lú.

36 Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣáálẹ́, wòlíì Èlíjà sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.

37 Gbọ́ ti èmi, Olúwa, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lè mọ̀ pé ìwọ Olúwa ni Ọlọ́run àti pé ìwọ tún yí ọkàn wọn padà.”

38 Nígbà náà ni iná Olúwa bọ́ sílẹ̀, ó sì sun ẹbọ síṣun náà àti igi, àti àwọn Òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì tún lá omi tí ń bẹ nínú yàrà náà.

39 Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, “Olúwa, òun ni Ọlọ́run! Olúwa, òun ni Ọlọ́run!”

40 Nígbà náà ni Èlíjà sì pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn wòlíì Báálì. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sá lọ!” Wọ́n sì mú wọn, Èlíjà sì mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí odò Kíṣónì, ó sì pa wọ́n níbẹ̀.

41 Èlíjà sì wí fún Áhábù pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.”

42 Bẹ́ẹ̀ ni Áhábù gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ṣùgbọ́n Èlíjà gun orí òkè Kámẹ́lì lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀.

43 Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.”Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.”Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.”

44 Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọ̀sánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.”Èlíjà sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’ ”

45 Ó sì ṣe, nígbà díẹ̀ sí i, ọ̀run sì sú fún àwọsánmọ̀, ìjì sì dìde, òjò púpọ̀ sì rọ̀, Áhábù sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Jésírẹ́lì.

46 Agbára Olúwa sì ń bẹ lára Èlíjà; ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì ṣáré níwájú Áhábù títí dé Jésírẹ́lì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22