1 Ọba 12 BMY

Ísírẹ́lì Ṣọ̀tẹ̀ Sí Réhóbóámù

1 Réhóbóámù sì lọ sí Ṣékémù, nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba.

2 Nígbà tí Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó wà ní Éjíbítì síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Sólómónì ọba, ó sì wà ní Éjíbítì.

3 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jéróbóámù, òun àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì sì lọ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, wọ́n sì wí fún un pé:

4 “Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.”

5 Réhóbóámù sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.

6 Nígbà náà ni Réhóbóámù ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbààgbà tí ń dúró níwájú Sólómónì baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láàyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”

7 Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò má a ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”

8 Ṣùgbọ́n Réhóbóámù kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.

9 Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀?”

10 Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ.

11 Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàsán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”

12 Jéróbóámù àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Réhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.”

13 Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un,

14 Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo; Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i; Baba mi fi pàsán nà yín; Èmi yóò fí àkéekèe nà yín.”

15 Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì láti ẹnu Áhíjà ará Ṣílò ṣẹ.

16 Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé:ìpín wo ni àwa ní nínú Dáfídì,Ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jésè?Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì!Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì padà sí ilé wọn.

17 Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé nínú ìlú Júdà, Réhóbóámù jọba lóri wọn síbẹ̀.

18 Réhóbóámù ọba rán Ádórámù jáde, ẹni tí ń ṣe olórí iṣẹ́ irú, ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa, Réhóbóámù ọba, yára láti gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì sá lọ sí Jérúsálẹ́mù.

19 Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.

20 Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ pé Jéróbóámù ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dáfídì lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Júdà nìkan.

21 Nígbà tí Réhóbóámù sì dé sí Jérúsálẹ́mù, ó kó gbogbo ilé Júdà jọ, àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Ísírẹ́lì jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì.

22 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Sémáíàh ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé:

23 “Sọ fún Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì, ọba Júdà àti fún gbogbo ilé Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì, àti fún àwọn ènìyàn tó kù wí pé,

24 ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì. Ẹ padà, olúkúlùkù yín sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

Ẹgbọ̀rọ̀ Màlúù Wúrà Ní Bétélì àti Dánì

25 Nígbà náà ni Jéróbóámù kọ́ Ṣékémù ní òkè Éfúráímù, ó sì ń gbé inú rẹ̀. Láti ibẹ̀ ó sì jáde lọ, ó sì kọ́ Pénúélì.

26 Jéróbóámù rò nínú ara rẹ̀ pé, “Ìjọba náà yóò padà nísinsìnyìí sí ilé Dáfídì.

27 Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún Olúwa wọn, Réhóbóámù ọba Júdà. Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Réhóbóámù ọba Júdà lọ.”

28 Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Ísírẹ́lì, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.”

29 Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Bétélì, àti èkejì ní Dánì.

30 Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dánì láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀.

31 Jéróbóámù sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Léfì.

32 Ó sì dá àṣè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àṣè tí ó wà ní Júdà, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Bétélì, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Bétélì.

33 Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Bétélì. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22