1 Ọba 4 BMY

Àwọn Aláṣẹ Àti Alákòóso Sólómónì

1 Sólómónì ọba sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

2 Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀:Ásáríyà ọmọ Ṣádókù àlùfáà:

3 Élíhóréfù àti Áhíjà àwọn ọmọ Ṣísánì akọ̀wé;Jèhósáfátì ọmọ Áhílúdì ni akọ̀wé ìlú;

4 Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni olórí ogun;Sádókù àti Ábíátarì ni àwọn àlùfáà;

5 Ásáríyà ọmọ Nátanì ni olórí àwọn agbègbè;Sóbúdù ọmọ Nátanì, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn;

6 Áhísárì ni olùtọ́jú ààfin;Ádónírámù ọmọ Ábídà ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú

7 Sólómónì sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.

8 Orúkọ wọn ni wọ̀nyí:Bénhúrì ní ìlú olókè Éfúráímù.

9 Beni-Dékérì ní Mákásì, Ṣáíbímù, Bẹti-Sémésì, àti Eloni-Bétíhánánì;

10 Beni-Hésédì, ní Árúbótì; tirẹ̀ ni Sókò àti gbogbo ilẹ̀ Héférì ń ṣe;

11 Beni-Ábínádábù, ní Napoti Dórì; òun ni ó fẹ́ Táfátì ọmọbìnrin Sólómónì ní aya.

12 Báánà ọmọ Áhílúdì, ní Táánákì àti Mégídò, àti ní gbogbo Bétísánì tí ń bẹ níhà Saritanà níṣàlẹ̀ Jésérẹ́lì, láti Bétísánì dé Abeli-Méhólà títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jókínéámù;

13 Bẹni-Gébérì ní Rámótì-Gílíádì; tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jáírì ọmọ Mànásè tí ń bẹ ní Gílíádì, tirẹ̀ sì ni agbégbé Ágóbù, tí ń bẹ ní Básánì, ọgọ́ta (60) ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin.

14 Áhínádábù ọmọ Ídò ní Máhánáímù

15 Áhímásì ní Náfítalì; ó fẹ́ Básémátì ọmọbìnrin Sólómónì ní aya;

16 Báánà ọmọ Húṣáì ní Ásérì àti ní Álótì;

17 Jèhósáfátì ọmọ Párúhà ni ó wà ní Ísákárì;

18 Síméì ọmọ Élà ni Bẹ́ńjámínì;

19 Gébérì ọmọ Úrì ní Gílíádì; orílẹ̀ èdè Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì àti orílẹ̀ èdè Ógù ọba Básánì. Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.

Oúnjẹ Sólómónì lójoojúmọ́

20 Àwọn ènìyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.

21 Sólómónì sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ijọba láti odò Éjíbítì títí dé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì, àti títí dé etí ilẹ̀ Éjíbítì. Àwọn orílẹ̀ èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Sólómónì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

22 Oúnjẹ Sólómónì fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n (30) ìyẹ̀fun kíkúná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun,

23 Màlúù mẹ́wàá (10) tí ó sanra, àti ogún (20) màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti egbin, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.

24 Nítorí òun ni ó ṣakóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Éfúrátì, láti Tífísà títí dé Gásà, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó káàkiri.

25 Nígbà ayé Sólómónì, Júdà àti Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Béríṣébà, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.

26 Sólómónì sì ní ẹgbàajì (40,000) ilé ẹsin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàafà (12,000) ẹlẹ́sin.

27 Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Sólómónì ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá síbi tábìlì ọba, wọ́n sì ríi pé ohun kankan kò ṣẹ́ kù.

28 Wọ́n tún máa ń mú ọkà báálì àti kóríko fún ẹsin àti fún ẹsin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀.

Ọgbọ́n Sólómónì

29 Ọlọ́run sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòrò òye tí a kò le è fi wé iyanrìn tí ó wà létí òkun.

30 Ọgbọ́n Sólómónì sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Éjíbítì lọ.

31 Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Étanì, ará Ésírà, àti Hémánì àti Kálíkólì, àti Darà àwọn ọmọ Máhólì lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀ èdè yíká.

32 Ó sì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005).

33 Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti Kédárì tí ń bẹ ní Lébánónì dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.

34 Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀ èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì, tí àwọn ọba ayé ń rán, tí ó ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22