48 ó sì wí pé, ‘Ògo ni fún Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti jẹ́ kí ojú mi rí ẹnìkan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ mi lónìí.’ ”
49 Nígbà náà ni gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ Àdóníjà dìde ní ìdágìrì, wọ́n sì túká.
50 Ṣùgbọ́n Àdóníjà sì bẹ̀rù Sólómónì, ó lọ, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.
51 Nígbà náà ni a sì sọ fún Sólómónì pé, “Adóníjà bẹ̀rù Sólómónì Ọba, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí ọba Sólómónì búra fún mi lónìí pé, òun kì yóò fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’ ”
52 Sólómónì sì dáhùn pé, “Bí ó bá fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, irun orí rẹ̀ kan kì yóò sì bọ́ sílẹ̀; ṣùgbọ́n bí a bá rí búburú kan ní ọwọ́ rẹ̀ òun yóò kú.”
53 Nígbà náà ni Sólómónì ọba rán àwọn ènìyàn, wọ́n sì mú un sọ̀kalẹ̀ láti ibi pẹpẹ wá. Àdóníjà sì wá, ó sì foríbalẹ̀ fún Sólómónì ọba, Sólómónì sì wí pé, “Lọ ilé rẹ.”