15 Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Árábíà, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.
16 Sólómónì ọba sì ṣe igba (200) aṣà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan.
17 Ó sì tún ṣe ọ̀ọ́dúrún (300) aṣà wúrà lílù, pẹ̀lú òṣùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí aṣà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lébánónì.
18 Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ èyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó.
19 Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, èyín rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni irọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn.
20 Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ọ̀kọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí.
21 Gbogbo ohun èlò mímu Sólómónì ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lébánónì sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí ìkankan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkankan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.