1 Ọba 11:33-39 BMY

33 Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì, Kémósì òrìṣà àwọn ará Móábù, àti Mííkámù òrìṣà àwọn ọmọ Ámónì, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómónì ti ṣe.

34 “ ‘Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Sólómónì; èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́.

35 Èmi yóò gba ìjọba náà ní ọwọ́ ọmọ rẹ̀, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ̀wàá fún ọ.

36 Èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa ní ìmọ́lẹ̀ níwájú mi nígbà gbogbo ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn láti fi orúkọ mi síbẹ̀.

37 Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, Èmi yóò mú ọ, ìwọ yóò sì jọba lórí ohun gbogbo tí ọkàn rẹ ń fẹ́; ìwọ yóò jọba lórí Ísírẹ́lì.

38 Bí ìwọ bá ṣe gbogbo èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú mi nípa pípa òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí i Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò kọ́ ilé òtítọ́ fún ọ bí èyí tí mo kọ́ fún Dáfídì, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì fún ọ.

39 Èmi yóò sì rẹ irú ọmọ Dáfídì sílẹ̀ nítorí èyí, ṣùgbọ́n kì í ṣe títí láé.’ ”