17 A ti sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi níhìn-ín tàbí kí o padà lọ nípa ọ̀nà tí ìwọ bá wá.’ ”
18 Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, “Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Ańgẹ́lì sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé: ‘Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi.’ ” (Ṣùgbọ́n ó purọ́ fún un ni.)
19 Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀.
20 Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé;
21 Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Júdà wá wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́.
22 Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ”
23 Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un.