1 Ní àkókò náà Ábíjà ọmọ Jéróbóámù sì ṣàìsàn,
2 Jéróbóámù sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́ ní aya Jéróbóámù. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣílò. Áhíjà wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jọba lórí àwọn ènìyàn yìí.
3 Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì ṣọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.”
4 Bẹ́ẹ̀ ni aya Jéróbóámù sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Áhíjà ní Ṣílò.Áhíjà kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀.
5 Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Áhíjà pé, “Kíyèsí i, aya Jéróbóámù ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”
6 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Áhíjà sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jéróbóámù. Kíló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ.
7 Lọ, sọ fún Jéróbóámù pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórì lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.