22 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń tọ Ómírì lẹ́yìn borí àwọn tí ń tọ Tíbínì ọmọ Gínátì lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni Tíbínì kú, Ómírì sì jọba.
23 Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, Ómírì bẹ̀rẹ̀ sí ń jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní ọdún méjìlá, ọdún mẹ́fà ní Tírisà.
24 Ó sì ra òkè Samáríà lọ́wọ́ Sérérì ní talẹ́ńtì méjì fàdákà, ó sì kọ́ ìlú sórí rẹ̀, ó sì pe ìlú náà ní Samáríà, nípa orúkọ Sémérì, orúkọ ẹni tí ó kọ́kọ́ ni òkè náà.
25 Ṣùgbọ́n Ómírì sì ṣe búburú níwájú Olúwa, Ó sì ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ.
26 Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jéróbóámù ọmọ Nébátì àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, láti fi ohun asán wọn mú Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.
27 Ìyòókù ìṣe àti ohun tí ó ṣe, àti agbára rẹ tí ó fi hàn, a kò ha kọ, wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?
28 Ómírì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní Ṣamáríà. Áhábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.