29 Ní ọdún kejìdínlógójì Áṣà ọba Júdà, Áhábù ọmọ Ómírì jọba ní Isireli, o si jọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún méjìlélógún.
30 Áhábù ọmọ Ómírì sì ṣe búburú ní ojú Olúwa ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ.
31 Ó sì ṣe bí ẹni pé ó ṣe ohun kékeré fún un láti máa rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, ó sì mú Jésébélì, ọmọbìnrin Étíbáálì, ọba àwọn ará Sídónì ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń sin Báálì, ó sì bọ ọ́.
32 Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Báálì nínú ilé Báálì tí ó kọ́ sí Samáríà.
33 Áhábù sì tún ṣe ère òrìṣà kan, ó sì ṣe púpọ̀ láti mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú ju èyí tí gbogbo ọba Ísírẹ́lì tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ ti ṣe lọ.
34 Ní ìgbà ayé Áhábù, Híélì ará Bétélì kọ́ Jẹ́ríkò. Ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀ ní Ábírámù, àkọ́bí rẹ, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn ibodè rẹ̀ kọ́ ní Ṣégúdù àbíkẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Jóṣúà ọmọ Núnì sọ.