1 Ọba 18:23-29 BMY

23 Ẹ fún wa ní ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì ké e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i.

24 Nígbà náà ẹ ó sì képe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì képe orúkọ Olúwa. Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run.”Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára.”

25 Èlíjà sì wí fún àwọn wòlíì Báálì wí pé, “Ẹ yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀. Ẹ ké pe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i.”

26 Nígbà náà ni wọ́n sì mú ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù náà, tí a ti fi fún wọn, wọ́n sì ṣe é.Nígbà náà ni wọ́n sì képe orúkọ Báálì láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan wí pé, “Báálì! Dáwa lóhùn!” Wọ́n sì ń kégbe. Ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn; kò sí ẹnìkan tí ó sì dáhùn. Wọ́n sì jó yí pẹpẹ náà ká, èyí tí wọ́n tẹ́.

27 Ní ọ̀sán gangan, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, “Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run ṣá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò. Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i.”

28 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn.

29 Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì sí ìdáhùn, kò sì sí ẹni tí ó kà á sí.