1 Áhábù sì sọ gbogbo ohun tí Èlíjà ti ṣe fún Jésébélì àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì.
2 Nítorí náà Jésébélì rán oníṣẹ́ kan sí Èlíjà wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.”
3 Èlíjà sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Bíáṣébà ti Júdà, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀,
4 nígbà tí òun tìkárarẹ̀ sì lọ ní ìrìn ojọ́ kan sí ihà, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, Olúwa, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ”