20 Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Árámù sì sá, Ísírẹ́lì sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì sálà lórí ẹsin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin.
21 Ọba Ísírẹ́lì sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Árámù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
22 Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Árámù yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”
23 Àwọn ìránṣẹ́ ọba Árámù sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, Ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú.
24 Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe: Mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi olórí ogun sí ipò wọn.
25 Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Ísírẹ́lì jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba ti wọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.
26 Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Bẹni-Hádádì ka iye àwọn ará Árámù, ó sì gòkè lọ sí Áfékì, láti bá Ísírẹ́lì jagun.