1 Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Nábótì ará Jésérẹ́lì sì ní ọgbà àjàrà kan ní Jésérẹ́lì, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà.
2 Áhábù sì wí fún Nábótì pé, “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ, kí èmi kí ó fi ṣe ọgbà-ewébẹ̀, nítorí tí ó súnmọ́ tòsí ilé mi; Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀; tàbí bí ó bá sì dára ní ojú rẹ, èmi yóò fi iye owó rẹ̀ fún ọ.”
3 Ṣùgbọ́n Nábótì wí fún Áhábù pé, “Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn bàbá mi fún ọ.”
4 Áhábù sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Nábótì ará Jésérẹ́lì sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn bàbá mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun.
5 Jésébélì aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, Èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?”
6 Ó sì dá a lóhùn pé, “Nítorí tí mo wí fún Nábótì ará Jésérẹ́lì pé, ‘Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, Èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó wí pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’ ”