1 Fún ọdún mẹ́ta kò sì sí ogun láàrin Árámù àti Ísírẹ́lì.
2 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹ́ta, Jèhósáfátì ọba Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti rí ọba Ísírẹ́lì.
3 Ọba Ísírẹ́lì sì ti wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ti wa ni Ramoti Gílíádì, àwa sì dákẹ́ síbẹ̀, a kò sì gbà á padà lọ́wọ́ ọba Árámù?”
4 Ó sì béèrè lọ́wọ́ Jèhósáfátì pé, “Ṣé ìwọ yóò bá mi lọ láti lọ bá Ramoti-Gílíádì jà?”Jèhóṣáfátì sì dá ọba Ísírẹ́lì lóhùn pé, “Èmi bí ìwọ, ènìyàn mi bí ènìyàn rẹ, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”
5 Ṣùgbọ́n Jèhósáfátì sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”
6 Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti-Gílíádì lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”