1 Ọba 22:3-9 BMY

3 Ọba Ísírẹ́lì sì ti wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ti wa ni Ramoti Gílíádì, àwa sì dákẹ́ síbẹ̀, a kò sì gbà á padà lọ́wọ́ ọba Árámù?”

4 Ó sì béèrè lọ́wọ́ Jèhósáfátì pé, “Ṣé ìwọ yóò bá mi lọ láti lọ bá Ramoti-Gílíádì jà?”Jèhóṣáfátì sì dá ọba Ísírẹ́lì lóhùn pé, “Èmi bí ìwọ, ènìyàn mi bí ènìyàn rẹ, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”

5 Ṣùgbọ́n Jèhósáfátì sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”

6 Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti-Gílíádì lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

7 Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì béèrè pé, “Ǹjẹ́ wòlíì Olúwa kan kò sí níhìn ín, tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

8 Ọba Ísírẹ́lì dá Jèhóṣáfátì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan sì wà, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa lè béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀ nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kan nípa mi, bí kò ṣe ibi. Míkáyà ọmọ Ímílà ni.”Jéhósáfátì sì wí pé, “Kí ọba má ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”

9 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì sì pe ìránṣẹ́ kan, ó sì wí pé, “Lọ yára mú Míkáyà, ọmọ Ímílà wá.”