1 Ọba 22:30-36 BMY

30 Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, “Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

31 Ọba Árámù ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n wí pé, “Ẹ má ṣe bá ẹnìkankan jà, ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, bí kò ṣe ọba Ísírẹ́lì nìkan.”

32 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jèhósáfátì, wọ́n sì wí pé, “Dájúdájú ọba Ísírẹ́lì ni èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ì yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhósáfátì sì kígbe sókè,

33 àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì padà kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

34 Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Ísírẹ́lì láàrin ìpàdé ẹ̀wù irin. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun. Èmi ti gbọgbẹ́.”

35 Ogun náà sì le ní ọjọ́ náà, a sì dá ọba dúró nínú kẹ̀kẹ́ kọjú sí àwọn ará Árámù. Ẹ̀jẹ̀ sì sàn jáde láti inú ọgbẹ́ rẹ̀ sí àárin kẹ̀kẹ́ náà, ó sì kú ní àṣálẹ́.

36 A sì kéde la ibùdó já ní àkókò ìwọ̀ oòrùn wí pé, “Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀!”