32 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jèhósáfátì, wọ́n sì wí pé, “Dájúdájú ọba Ísírẹ́lì ni èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ì yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhósáfátì sì kígbe sókè,
33 àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì padà kúrò lẹ́yìn rẹ̀.
34 Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Ísírẹ́lì láàrin ìpàdé ẹ̀wù irin. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun. Èmi ti gbọgbẹ́.”
35 Ogun náà sì le ní ọjọ́ náà, a sì dá ọba dúró nínú kẹ̀kẹ́ kọjú sí àwọn ará Árámù. Ẹ̀jẹ̀ sì sàn jáde láti inú ọgbẹ́ rẹ̀ sí àárin kẹ̀kẹ́ náà, ó sì kú ní àṣálẹ́.
36 A sì kéde la ibùdó já ní àkókò ìwọ̀ oòrùn wí pé, “Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀!”
37 Bẹ́ẹ̀ ni ọba kú, a sì gbé e wá sí Samáríà, wọ́n sì sin ín ní Samáríà.
38 Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samáríà, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rè, àwọn àgbérè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti sọ.