17 “Dáfídì baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
18 Ṣùgbọ́n Olúwa sì wí fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ.
19 Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde; òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’
20 “Olúwa sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́: Èmi sì ti rọ́pò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì báyìí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
21 Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí-ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú Olúwa tí ó ti bá àwọn baba wa dá nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.”
22 Sólómónì sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run.
23 Ó sì wí pé:“Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.