1 Ọba 8:32-38 BMY

32 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtọ́ láre, kí a sì fi ẹṣẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀.

33 “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí

34 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ jìn-ní, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn.

35 “Nígbà tí ọ̀run bá ṣé mọ́, tí kò sí òjò nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,

36 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jìn wọ́n, à ní Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní.

37 “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdú, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí àrùnkárùn tó lè wá,

38 nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí,