1 Réhóbóámù sì lọ sí Ṣékémù nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba.
2 Nígbà tí Jéróbóámù ọmọ Nébátì gbọ́ èyí ó wà ní Éjíbítì, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Sólómónì ó sì padà láti Éjíbítì.
3 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránsẹ́ sí Jéróbóámù àti òun àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì lọ sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù wọ́n sì wí fún pé:
4 “Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́.”
5 Réhóbóámù sì dáhùn pé, “ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn náà sì lọ.
6 Nígbà náà ni ọba Réhóbóámù fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbààgbà tí ó ti ń sin Baba rẹ̀ Sólómónì nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”.