31 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jéhóṣáfátì, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Ísírẹ́lì.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jéhóṣáfátì kégbe sókè, Olúwa sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,
32 Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ ríi wí pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró.
33 Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Ísírẹ́lì láàárin ìpàdé ẹ̀wù ìrin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.”
34 Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ síi, ọba Ísírẹ́lì dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Síríà títí ó fi di àsaálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.