2 Kíróníkà 18:5-11 BMY

5 Bẹ́ẹ̀ ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì papọ̀, irínwó (4,000) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Rámótì Gélíádì tàbi kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?”“Lọ,” wọ́n dáhùn, “nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

6 Ṣùgbọ́n Jehósáfátì béèrè pé, “Ṣé kò ha sí wòlíì Olúwa níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

7 Ọba Ìsírélì dá Jehóṣáfatì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ì bá tún béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorì kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Míkáyà ọmọ Ímílà.”“Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀,” Jehóṣáfátì sì dá lóhùn.

8 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹmú Míkáyà ọmọ Ímílà kí ó yára wá.”

9 Wọ́n wọ aṣọ Ìgúnwà wọn, ọba Ísírẹ́lì àti Jehóṣáfátì ọba Júdà wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu bodè Samaríà, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

10 Nísinsin yìí Sedekáyà ọmọ Kénánà sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Síríà títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.”

11 Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ̀lẹ́ ní àkókò kan náà, “Wọ́n sì wí pé, dojúkọ Rámótì Gílíádì ìwọ yóò sì ṣẹ́gun,” wọ́n wí pé, “nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”