1 Nígbà tí Jéhóṣáfátì ọba Júdà padà ní àlàáfíà sí ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù,
2 Jéhù aríran, ọmọ Hánánì jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Sé ìwọ yóò máa ran ènìyàn búburú lọ́wọ́, kí o sì fẹ́ràn àwọn tí ó kórìíra Olúwa? Nítorí èyí, ìbínú Olúwa wà lórí wa.
3 Bí ó ti wù kí ó rí, ohun rere wà nínú rẹ, nítorí tí ìwọ ti mú àwọn ilé àwọn ère òrìṣà kúrò, tí o sì múra ọkàn rẹ láti wá Ọlọ́run.”
4 Jéhóṣáfátì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ó sì jáde lọ padà láàárin àwọn ènìyàn láti Béríṣébà dé òkè ìlú Éfúráímù, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn.
5 Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi, Júdà.
6 Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsí ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́.