13 “Èmi ń rán Húrámì-Abi, sí ọ ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ ńlá,
14 Ẹni tí ìyá rẹ̀ wá láti Dánì àti tí Baba a rẹ̀ wá láti Tírè. A kọ́ ọ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti igi, àti pẹ̀lú àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ ọ̀run àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára. Ó ní ìmọ̀ nínú gbogbo oríṣìí iṣẹ́ fínfín. Ó sì le ṣe àwárí irú ẹ̀yà kẹ́yà tí a bá fún un. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà pẹ̀lú àwọn ènìyàn Olúwa mi, Dáfídì baba a rẹ.
15 “Nísinsin yìí, jẹ́ kí Olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àlìkámọ̀ àti bálì àti òróró Ólífì náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí.
16 Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lébanónì tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Jópà. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.”
17 Sólómónì ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dáfídì ti ṣe; a sì ka iye wọn sí (153,600) ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbéjì-lélọ́gbọ̀n.
18 Ó sì yan ẹgbàá márùndínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbéjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́.