12 Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojú kọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”
13 Gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kékèké, dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.
14 Nígbà náà, ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jáhásíẹ̀lì ọmọ Sékáríà, ọmọ Bénáyà, ọmọ Jéíèlì, ọmọ Mátaníyà ọmọ Léfì àti ọmọ Ásáfù, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dìde dúró láàrin àpèjọ ènìyàn.
15 Ó sì wí pé, “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jéhóṣáfátì àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù! Èyí ní ohun tí Olúwa sọ wí pé kí a ṣe: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí. Nítorí, ogun ìjà náà kìí ṣe ti yín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni.
16 Ní ọla, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú ibi ṣíṣe wa, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú ihà Jérúẹ́lì.
17 Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní àyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojú kọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”
18 Jóhóṣáfátì tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa.