1 Àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù mú Áhásáyà, ọmọ Jéhórámù tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Árábù sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà. Bẹ́ẹ̀ ni Áhásáyà ọmọ Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní Jọba.
2 Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún kan. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Ataláyà, Ọmọ-ọmọbìnrin Ómírì.
3 Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Áhábù. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú.
4 Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú bàbá a rẹ̀, wọ́n di olùgbani lámọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀.
5 Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Jórámì ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì láti gbógun ti Háṣáélì ọba Árámì ní Rámótì Gílíádì. Àwọn ará Árámì ṣá Jórámì lọ́gbẹ́;
6 Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jésírẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rámótì ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Háṣáélì ọba ÁrámìNígbà náà, Áhásáyà, ọmọ Jehórámì ọba Júdà lọ sí Jésírẹ́lì láti lọ rí Jórámì ọmọ Áhábù nítorí a ti ṣáa lọ́gbẹ́.
7 Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Áhásáyà sí Jórámí, Ọlọ́run mú ìṣubú Áhásáyà wá. Nígbà tí Áhásáyà dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jórámì láti lọ bá Jéhù ọmọ Nímísì, ẹni tí Olúwa ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Áhábù run.