2 Kíróníkà 22:5-11 BMY

5 Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Jórámì ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì láti gbógun ti Háṣáélì ọba Árámì ní Rámótì Gílíádì. Àwọn ará Árámì ṣá Jórámì lọ́gbẹ́;

6 Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jésírẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rámótì ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Háṣáélì ọba ÁrámìNígbà náà, Áhásáyà, ọmọ Jehórámì ọba Júdà lọ sí Jésírẹ́lì láti lọ rí Jórámì ọmọ Áhábù nítorí a ti ṣáa lọ́gbẹ́.

7 Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Áhásáyà sí Jórámí, Ọlọ́run mú ìṣubú Áhásáyà wá. Nígbà tí Áhásáyà dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jórámì láti lọ bá Jéhù ọmọ Nímísì, ẹni tí Olúwa ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Áhábù run.

8 Nígbà tí Jéhù ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Áhábù. Ó rí ọmọbìrin ọba ti Júdà àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Áhásì. Tí ó ń dásí Áhásáyà, ó sì pa wọ́n.

9 Ó lọ làti wá Áhásáyà, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sá pamọ́ ní Saaríà. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jéhù, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé “Ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ni, ẹni tí ó wá Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Áhásáyà tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró.

10 Nígbà tí Ataláyà ìyá Áhásáyà ríi wí pé ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀ṣíwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba ti ilẹ̀ Júdà run.

11 Ṣùgbọ́n Jehóṣẹ́bà ọmọbìnrin ọba Jéhórámù mú Jóásì, ọmọkùnrin Áhásáyà ó sì jíi gbé lọ kúrò láàrin àwọn ọmọ-obìrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa. Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù. Nítorí Jèhóṣebà ọmọbìnrin ọba Jehórámì àti ìyàwó àlùfáà Jéhóiádà jẹ́ arábìnrin Áhásáyà. Ó fi ọmọ naà pamọ́ kúrò fún Ataláyà, kí ó má ba à pa á.