13 “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” wọ́n wí pé, “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú Olúwa, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi pupọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Ísírẹ́lì.”
14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógún sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn.
15 Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lu orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbékùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòǹhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọ̀n tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ, wọ́n sì padà sí Samaríà.
16 Ní àkókò ìgbà náà, ọba Áhásì ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà fún ìrànlọ́wọ́.
17 Àwọn ará Édómù sì tún padà wá láti kọlu Júdà kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ.
18 Nígbà tí àwọn ará Fílístínì sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n nì àti síhà gúsù Júdà. Wọ́n sẹ́gun wọ́n sì gba Béti-ṣémésì, Áíjálónì àti Gédérótì, àti Sókò, Tímínà, a ri Gímísò, pẹ̀lú ìletò wọn.
19 Olúwa sì rẹ Júdà sílẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ó sọ Júdà di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì se ìrékọjá gidigidi sí Olúwa.