33 Àwọn ohun ìyà sí mímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta màlúù, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn.
34 Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣe náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Léfì ṣe olóòtọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́.
35 Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun-mímu fún ẹbọ sísun.Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún dá ti iṣẹ́-ìsìn ilé Olúwa sílẹ̀.
36 Heṣekáyà sì yọ̀, àti gbogbo ènìyàn pé, Ọlọ́run ti múra àwọn ènìyàn náà sílẹ̀, nítorí lójijì ni a ṣe nǹkan náà.