13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní oṣù kejì.
14 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kídírónì.
15 Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹ́rinlà oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa.
16 Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Léfì.
17 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: wọn pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa.
18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Éfíráimù àti Mánásè, Ísákárì, àti Sébúlúnì kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì íṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Heṣekáyà bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjin olúkúlùkù,
19 Tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì íṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́