9 Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, ó sì fún-un ní owó náà tí ó mú wá sí ínú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Léfì ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́-ẹnú-ọ̀nà-ìbòdè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Ménásè Éfíráímù àti láti ọ̀dọ̀ Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì wọ́n sì padà sí Jérúsálẹ́mù.
10 Nígbà náà wọn si fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ṣe, tí wọ́n sì ń ṣìṣẹ́ ní ilé Olúwa.
11 Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn ọlọ́nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Júdà ti gbà láti tẹ́ ilé tí wọ́n ti bàjẹ́.
12 Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́ lórí wọn, láti darí wọn ní Jáhátì àti Obadíà, àwọn ọmọ Léfì láti Mérárì, àti Sekaríà àti Mèsúlámù, sọ̀kalẹ̀ láti Kónátì àwọn ọmọ Léfì gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin.
13 Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìsẹ́ láti ibisẹ́ si ibisẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì sì ní alákọ̀wé, olùtọ́jú àti olùsọ́nà.
14 Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hílkíà àlùfáà sì rí ìwe òfin Olúwa tí a ti fi fún-un láti ọwọ́ Mósè.
15 Hílíkíyà sì wí fún Ṣáfánì akọ̀wé pé, “Èmi ti rí ìwe òfin nínú ilé Olúwa.” Ó sì fi fún Ṣáfánì.