2 Kíróníkà 35:8-14 BMY

8 Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn Àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Hílíkíyà, Sekaríà àti Jéhíélì, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún ẹran ọ̀sìn (300).

9 Àti pẹ̀lú Koníà àti pẹ̀lú Ṣémíà àti Nàtaníẹ́lì, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabíà, Jélíélì àti Joábádì olórí àwọn ọmọ Léfì, ó sì pèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹbọ ìrékọjá (500) àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Léfì.

10 Nítorí náà, a múra ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì dúró ní ipò wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nípa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á lásẹ.

11 Ní ti àjọ ìrékọjá a sì pa ẹran, àwọn àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbé sí ọwọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ Léfì sì bo ẹranko.

12 Wọ́n sì ya àwọn ẹbọ sísún sí apá kan láti fi wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ìdílé àwọn ènìyàn láti rúbọ sí Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọọ́ sínú ìwé Mósè. Wọ́n sì se bákan náà pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn.

13 Wọ́n sì fi sun àjọ ìrékọjá lórí iná Gẹ́gẹ́ bí ìlànà, wọ́n sì bọ ẹbọ mímọ́ nínú ìkòkò, nínú odù àti nínú agbada, wọ́n sì pín wọn kíákía fún gbogbo àwọn ènìyàn.

14 Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Árónì, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àsálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Árónì àlùfáà.