12 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ ko si rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremíà wòlíì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa.
13 Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadinésárì pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ẹni tí ọrùn rẹ̀ wàkì, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
14 Síwájú síi gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀ èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.
15 Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránsẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣíwájú àti ṣíwájú síi, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìransẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ sẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run ṣe ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì sí àtúnṣe.
17 Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Bábílónì tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdé bìnrin, wúndíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadinésárì lọ́wọ́.
18 Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Bábílónì, níńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀.