20 Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Bábílónì àwọn tí ó rí ibi sá láti ẹnu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Pásíà fi gba agbára.
21 Ìlẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí ó fi di àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúsẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremíà.
22 Ní ọdún kín-ín-ní Kírúsì ọba Pásíà, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremáyà sọ báà le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kírúsì ọba Pásíà láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.
23 “Èyí ni ohun tí Kérúsì ọba Pásíà sọ wí pé:“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jérúsálẹ́mù ti Júdà. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”